Monday, 4 November 2013

Igbeyawo ni ile Yoruba je ohun to se pataki julo ni ile Yoruba. Eniti ko ba se iyawo ko to ko lo si ile oko, awon Yoruba ka iru obinrin bee gegebi ale okunrin naa. Sugbon, bawo lase n se igbeyawo ni ile Yoruba gangan? Okunrin yio ti foju sita lati wa obinrin ti o wun un, obinrin to ni iwa to si tun ni ewa pelu esin, awon mejeeji yio si jo soro po, leyin ti oro won ba ti wo, arakunrin yii yio so fun awon obi  re wipe "mo ti ri omo-binrin ti mo fe fe e", e wa lo ba mi wo o! Awon obi arakunrin naa yio si jade lo sile awon obi obinrin lati lo se awon eto to ye.......Eyi lo wa difa fun eto igbeyawo alarinrin laarin ABDUL RASHEED OJELABI ti Inagije re n je 'ORE-OBA' (Okan lara awon gbajugbaja sorosoro ile-ise radio ati ti telifisan lorile ede yi) ati Iyawo re OMOSHALEWA BALIKIS BAKARE, ti o ti wa di aya OJELABI bayi, eleyi ti o waye ni ojo karun, osu kewa, odun 2013 ni ilu Abeokuta, Ipinle Ogun. Die re e lara awon aworan ojo naa
Eyi wun wa o, iyawo  n de fila fun oko re......e wo erin kee-kee lenu oko iyawo, a fi bi igba ti eniyan ba ri owo he.


E je kajo gboju ayo soke wo Oko ati Iyawo bi oju won se n dan lojo nnkan eye won.....Asa Yoruba n bayin dupe ooo

Oko iyawo ree ooooo.....o ti kuro ninu egbe baba-n -daa-gbe, iya-n -yoo-wa

Al-qurian ni emi yan laayo ni temi, ki olorun se ibujoko mi ni ibujoko ayo

iyawo n fi oruka igbeyawo han awon ebi ati ara.

Alhaji Ayeloyun lo fi ilu ati orin dara nijo igbeyawo naa.... ki olorun bawa duro ti awon idile titun yi.

No comments:

Post a Comment