Monday, 2 December 2013

YO'BA MO'ODUA: Ewì Ọmọge Ìwòyí - Girls of now-a-days

YO'BA MO'ODUA: Ewì Ọmọge Ìwòyí - Girls of now-a-days: Hello friend, have you voted for yours truly  @yobamoodua  for the award of the Best Topical Blog Award in the Nigerian Blog Awards 2013....

Monday, 18 November 2013

             ASO ANKARA

Aso ankara ti d'aye ojo ti pe, bee ona ti jin pelu. Nigba kan ri, leyin ki a fi aso ankara ran ewu s'orun, ko tun si ohun meji ti a tun n fi ankara se mo, Sugbon bi ojo de n gori ojo,ni imo tun gori imo,bee ni awon ohun otun tun n d'aye, lo difa fun aso ankara to wa di ohun ti o gbajumo julo ninu gbogbo awon oniruuru aso towa nile yooba. Orisiri awon eso ara(accessories)ni won tun ti n fi aso ankara se bayi, ko fe e si eso ara kan ti won ko le fi aso ankara se bayi nile yooba, awon aloku aso (pieces) wa di ohun ti awon ransoranso tun n naani, ti won n ta fun awon eeyan lati fi se eso ara bii:egba orun, oruka owo, bata, baagi, beliti, tayi (tie) ati bee bee lo. E wo aworan awon nnkan wonyi

Oniruuru Baagi ti a se pelu Aso Ankara

Awon Bata, Egba owo ati Oruka owo ti a fi Ankara se

Beliti alawo Ankara

Baagi ti a se pelu Ankara alawo yelo ati bulu

Ewo Egba orun ti a sinpo pelu Ankara

Bata giga ti a se pelu Ankara

Eekannna igbalode ti a se pelu awo ankara

Tayi (tie) ti a fi aso ankara se

Eso ti a fi n se irun loge

Bata ti a fi Ankara da lara

Pilo ori Aga(Throw Pilow) ti a fi Ankara se

Ankara ti gbayi, o gbeye, ni ile kaaro-o-jiire, ati ni gbogbo orile ede agbaye patapata


Monday, 4 November 2013

Igbeyawo ni ile Yoruba je ohun to se pataki julo ni ile Yoruba. Eniti ko ba se iyawo ko to ko lo si ile oko, awon Yoruba ka iru obinrin bee gegebi ale okunrin naa. Sugbon, bawo lase n se igbeyawo ni ile Yoruba gangan? Okunrin yio ti foju sita lati wa obinrin ti o wun un, obinrin to ni iwa to si tun ni ewa pelu esin, awon mejeeji yio si jo soro po, leyin ti oro won ba ti wo, arakunrin yii yio so fun awon obi  re wipe "mo ti ri omo-binrin ti mo fe fe e", e wa lo ba mi wo o! Awon obi arakunrin naa yio si jade lo sile awon obi obinrin lati lo se awon eto to ye.......Eyi lo wa difa fun eto igbeyawo alarinrin laarin ABDUL RASHEED OJELABI ti Inagije re n je 'ORE-OBA' (Okan lara awon gbajugbaja sorosoro ile-ise radio ati ti telifisan lorile ede yi) ati Iyawo re OMOSHALEWA BALIKIS BAKARE, ti o ti wa di aya OJELABI bayi, eleyi ti o waye ni ojo karun, osu kewa, odun 2013 ni ilu Abeokuta, Ipinle Ogun. Die re e lara awon aworan ojo naa
Eyi wun wa o, iyawo  n de fila fun oko re......e wo erin kee-kee lenu oko iyawo, a fi bi igba ti eniyan ba ri owo he.


E je kajo gboju ayo soke wo Oko ati Iyawo bi oju won se n dan lojo nnkan eye won.....Asa Yoruba n bayin dupe ooo

Oko iyawo ree ooooo.....o ti kuro ninu egbe baba-n -daa-gbe, iya-n -yoo-wa

Al-qurian ni emi yan laayo ni temi, ki olorun se ibujoko mi ni ibujoko ayo

iyawo n fi oruka igbeyawo han awon ebi ati ara.

Alhaji Ayeloyun lo fi ilu ati orin dara nijo igbeyawo naa.... ki olorun bawa duro ti awon idile titun yi.

Saturday, 12 October 2013

Awon aworan eto Igbeyawo laarin Oluyemi Olanike Bukola ati Adeleye Olusesan

Igbeyawo je ohun iwuri ati idunnu fun gbogbo obinrin to ba fara bale gba eko awon obi, ki o to sa to okunrin lo....Ojo pataki ni ojo igbeyawo maa n je fun awa obinrin, koda, ojo idunu tun ni fun awon okunrin, paapaa julo awon obi oko ati ti iyawo.

wonyi ni awon aworan eto igbeyawo okan lara awon osise ile-ise Royal Fm 95.1 Ilorin (Oluyemi Olanike Bukola)
haa..emi ni mo fe arewa to rewa to eyi, ni ohun ti o wa lokan oko-iyawo to fi n woju aya re
Mo fe ohun ti mo le gbe (I marry who I can carry). (awada)
Eyin abelejayan, e lo wabi joko si nitori Adeleye Olusesan ti laya tie.
Eyin oloju-komu-kolo, e lo sempe, nitori Oluyemi Olanike Bukola ti loko tie
Awa mejeeji ti di okan lati oni lo..........ajosepo wa yio larinrin loruko JESU. AMIN

Wednesday, 11 September 2013

Aso wiwo ni ti ona asa Yoruba je ohun to ma n bu kun ewa obinrin. E je ka jo gbe asa ile wa laruge.








Gbigbe asa ile Yoruba ga je nnkan ti o je awon eniyan kan logun lagbole ise sorosoro, lojuna ati ri wipe a se adapada awon ohun ti o ti sonu ninu asa ile wa, paapaa julo nipase olaju. Bi a ba woo daradara, a o ri wipe, ko si eni ti o wo aso ile Yoruba ti ko ni se regi lara re. Wonyi ni aworan awon omo Yoruba atata, ti won n fi amura ati isesi won gbe asa ile Yoruba Laruge. A ko awon aworan yi jo nibi ayeye IGBELARUGE ASA ti okan lara awon sorosoro 'Bebe Musiliu' ati City People Media Group se agbateru re , fun ifami-eye-dani-lola ati sise agbajade awo orin 'Ogodo Egba' ni ojo aiku, ojo kejo, osu kesan, odun 2013, ni daktad event centre, ibara abeokuta.